Ààrẹ Muhammadu Buhari Gba Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Sí Ipò Alága Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC Lórílẹ̀-Èdè Nàìjíríà Ní Àlejò
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gba àwọn tó ń fìfẹ́ hàn sí ipò alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àlejò ní Abuja, olú ìlú Nàìjíríà.
Alakoso atẹkun ayelujara Aarẹ, Bashir Ahmad sọ eyi di mimọ lori atẹkun ayelujara rẹ ni irọlẹ Ọjọbọ, Oṣu Kẹta Ọjọ kẹtalelogun, Ọdun 2022.
Bakan naa ni Gomina Ipinlẹ Yobe ati Alabojuto ati Alakoso Igbimọ Eto Apejọ APC, Mai Mala Buni, Alakoso awọn osisẹ aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari ati Akọwe ijọba apapọ, Ọgbẹni Boss Mustapha wa lori ijoko nibi apejọ naa.
Leave a Reply