Ààrẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù agbègbè mẹ́rin ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaura ní ìpínlẹ̀ Kaduna; léèyí tó jẹ́ wípé àwọn ọmọ ogun méjì àti àwọn míràn ni wọ́n sekú pa látàrí ìkọlù náà.
Ó pè é ní “iwa ailaanu to buru jai” ti ko si àyè fún nínú àwùjọ ọ̀làjú kankan.
Ààrẹ Buhari ní òun wa lẹyin ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna àti àwọn ilé iṣẹ́ àbò tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ wọn láti tọpinpin àwọn janduku náà, kí wọ́n sì mú wọn wá sí ìdájọ́.
Ó kìlọ̀ lòdì sí ìgbẹ̀san, eyi tí ó lè yọrí sí ìwà ipá ati ikọlu síwájú sí i
Leave a Reply