Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ètò Ìse Ọ̀gbìn alaádàńlá nípa ètò ẹ̀rọ àti Olùdarí Fàdámà NG-CARES ní ìpínlẹ̀ Kwara, Ọ̀gbéni Busari Isiaka ti rọ ìjọba ní gbogbo ẹ̀ka ní orílè-èdè Nàìjíríà láti múra sí iṣẹ́ àgbẹ̀ ti alaádàńlá nípa ètò ẹ̀rọ kí oúnjẹ leè pọ̀ ní yanturu.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Isiaka so pé àìse ògbìn aládàá ńlá ti ètò ẹ̀rọ ló fa àìpọ̀ oúnjẹ; ó wá rọ ìjọba ìpínlẹ̀ àti àpapọ̀ àti àwọn afúnni lágbàyéé láti gbógun ti ìṣòro yìí.
Ó sọ èyí nígbà tó n ba àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Ìlọ̀rin, Olú ìlú Kwara. Ó sọ síwájú pé ọ̀dá owó, awo olókun náà tún fa èyí, kí ìjọba àti lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́ dìde ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀.
Ó tún kẹ́dùn àìsí ọ̀nà tó dára àti ohun èlò fún iṣyẹ Oko tí kò jẹ́ kí àgbẹ̀ rí èrè tó dára lórí iṣẹ́ wọn.
Leave a Reply