Take a fresh look at your lifestyle.

Àmọ̀tẹ́kùn Padà Sí Orílè Èdè India Lẹ́yìn Àádọ̀rin Ọdún

0 475

Eranko Àmọ̀tẹ́kùn yóò padà wá ní Orílẹ̀-èdè  India lẹ́yìn òpòlopò ọdún (1952) tí wọ́n ti kéde rẹ̀ pé o ti dágbére.

Àkójọpọ̀ ẹranko mẹ́jọ tó jọ olóńgbò ni yóò gúnlè láti Orílẹ̀-èdè Nàmíbíà láti sàmì sí ayẹyẹ ọjọ ìbí Ààrẹ Narendra Modi ni ọjó Abámẹ̀ta.
Wọn o kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àti ìtọ́jú wọn kí wọ́n tó dàwọ́n sínú ọgbà wọn ní àárín gbùngbùn orílè-èdè India.
Àmọ̀tẹ́kùn ti kọ́kọ́ darapọ̀ mọ́ àwọn eranko bíi Kìnìún, Ẹkùn nínú Igbó kí o tó di àwárì láti nǹkan bíi Àádọ̀rin Ọdún sẹ́yìn.
Ìgbà àkọ́kọ́ níyì tí wọn óò kó irú ọ̀pọ̀ eranko báyìí láti agbègbè kontinenti kan lọ ṣí òmíràn.
Ó kéré tán, ogún àmọ̀tẹ́kùn ni wọn ń kólọ sí orílè-èdè  India láti orílè èdè South Africa àti Nàmíbíà tí o ní ìdá kan nínú ìdámẹ̀ta ẹgbẹ̀rún méje àmọ̀tẹ́kùn gbogbo àgbáyé.
Abala àkọkọ tó jẹ́ abo márùn ún dín lọ́gọ̀rún àti akọ mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún.méjì sí mefa yóò kọ́kọ́ dé lati Windhoek ni orílè ede Nàmíbíà sí ìlú  Gwallor ti orílè ede India ní ọjó Abámẹ̀ta.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button