Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ Àringbùngbùn fòhùntẹ̀ lu àtúnyàn Touaderá

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

317

Ilé-ẹjọ́ ofin orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ Àringbùngbùn, ni ọjọ́ Ajé ti  fòhùntẹ̀ lu àseyege Ààrẹ Faustin-Archange Touadera, nínú ìdìbò Ààrẹ tó wáyé ní ọjọ́ kejìdín-lọ́gbọ̀n, léyìí tí ó jẹ́ kí ó máa lọ sí sáà kẹta.

Ni orukọ awọn eniyan Àringbùngbùn Adulawọ, ile ẹjọ olofin ti kede  Faustin Archange Touadera bii Aarẹ ti wọn dibo yan ni ipele akọkọ pẹlu ibo ida mẹtadin-lọgọrin le diẹ,” Aarẹ igbimọ olofin Jean-Pierre Waboe sọ bayii.

Alatakọ pataki Touadera , Adari Minisita nigba kan ri Anicet-Georges Dologuele, ni ibo ida mẹtala o le diẹ,leyi ti o jẹ esi ikẹyin ti igbimọ eleto idibo ṣafihan rẹ.

Ile ẹjọ ofin naa wa sọ pe oun kọ ibeere ti Dologuele gbekalẹ lẹyin ikede esi ibo.

Alatako miran, Adari Minisita nigba kan ri Henri-Marie Dondra, ti o ni ibo ida meji ati diẹ pere, gba fun aṣeyegeTouadera ti o si ni oun ko ni ẹjọ kankan lati pe’s victory and said he decided not to appeal.

Touadera, ti o jẹ ẹni ọdun mejidin-laadọrin, oluṣiro ti o gba ipo ni ọdun mẹwaa sẹyin, ṣe ipolongo lori ipese aabo to ṣe lori orilẹ-ede ti o ni ipenija ailalaafia.

Comments are closed.

button