Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Pè Fún Ètò Ìse Ọ̀gbin Alaádàńlá Ti Ètò Ẹ̀rọ Ní Orílè-Èdè Nàìjíríà

0 42

Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ètò Ìse Ọ̀gbìn alaádàńlá nípa  ètò ẹ̀rọ àti Olùdarí Fàdámà NG-CARES ní ìpínlẹ̀ Kwara, Ọ̀gbéni Busari Isiaka ti rọ ìjọba ní gbogbo ẹ̀ka ní orílè-èdè Nàìjíríà láti múra sí iṣẹ́ àgbẹ̀ ti alaádàńlá nípa  ètò ẹ̀rọ kí oúnjẹ leè pọ̀ ní yanturu.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Isiaka so pé àìse ògbìn aládàá ńlá ti ètò ẹ̀rọ ló fa  àìpọ̀ oúnjẹ; ó wá rọ ìjọba ìpínlẹ̀ àti àpapọ̀ àti àwọn afúnni lágbàyéé láti gbógun ti ìṣòro yìí.

Ó sọ èyí nígbà tó n ba àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Ìlọ̀rin, Olú ìlú Kwara. Ó sọ síwájú pé ọ̀dá owó, awo olókun náà tún fa èyí, kí ìjọba àti lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́ dìde ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀.

Ó tún kẹ́dùn àìsí ọ̀nà tó dára àti ohun èlò fún iṣyẹ Oko tí kò jẹ́ kí àgbẹ̀ rí èrè tó dára lórí iṣẹ́ wọn.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.