Láti ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ Ibà Àgbáyé ti ọdún yìí lónìí, Godrej Nigeria, àwọn tí wọ́n ń ṣe òògùn apakòkòròo GoodKnight Power Shots ti ń ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ilé-iṣẹ́ Ìlera ìjọba àpapọ̀ lábẹ́ẹ Ètò ìgbógun ti ààìsàn ibà ní Orílẹ̀-èdè (NMEP) Abuja, láti túnbọ̀ tẹramọ́ ìgbìyànjú wọn lórí pípa àìsàn ibà run ní Nàìjíríà nípasẹ̀ fífi òògùn ìpakòkòrò Goodknight ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tọrẹ fún ilé-iṣẹ́ náà.
Ile-iṣẹ naa gbe ẹbun ẹgbẹrun mẹwaa oogunapakokoro GoodKnight Power Shots fun ile-iṣẹ ijọba apapọ, nigba ti o ṣabẹwo si Minisita fun Ipinlẹ fun Ilera, Dokita Olorunnimbe Mamora, ni ilu Abuja ,gẹgẹ bi apakan iṣẹ rẹ lati ṣe iranti ayẹyẹ ayajọ ọjọ Iba Agbaye,ti ọdun 2022.
Nigba ti o n sọrọ lakoko ibẹwo naa, Mamora ṣe akiyesi pe iba ti pa awọn eniyan to pọ ti o si tun n tẹsiwaju lati pa eniyan sii ni Adulawọ ju kokoro HIV ati aarun Corona lọ.
Nipasẹ iwadi, Godrej ṣe agbejade oogun apakokoroo Goodknight Power Shot, fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti o si ti ko ipa pataki ni orilẹ-ede ni ọdun meji sẹyin.
Leave a Reply