Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Senegal Jáwé Olúborí Nípa Gbígbo Ewúro Soju Ikọ̀ Morrocco Ní Ìdíje Àsekágbá AFCON.

318

 

Ikọ̀ Teranga Lions of Senegal ní wọn gbade Olubori ajabori ti ilé Adúláwọ̀ fún ní igbà keji ninu ìtàn nipa gbígbo ewúro soju olugbalejo wọn, Morocco pèlú ayò kan dondo (1–0) lẹyìn afikun iseju ní pápá isere Stade Prince Moulay Abdellah ni Rabat.

Ikọ̀ Senegal bẹrẹ idije daradara ti wọn sì dárí idije náà ní abala akọkọ sugbọn asọ́le ikọ̀ Morrocco, Yassine Bounou kò fún wọn láàyè láti gbá bóòlù sì àwọ̀n. Ko fi àye gba bóòlù Gueye tó fòri kan àti ti Iliman Ndiaye gba láti wọlé.

Ní igbeyin, ọrẹ ọfẹ de fún ikọ̀ to gbalejo idije, Morocco láti mi àwọ̀n tìtì ní iṣẹju márùn ún ki abala akọkọ to pari látẹsẹ̀ Nayef Aguerd ti agbábọ́ọ̀lù Abdessamad Ezzalzouli gba síi sugbọn o kùnà láti yẹlé wò.

Ní iṣẹju mọ́kàndínláàdọ̀rún, arọ́pò, Ibrahim Mbaye ninu ikọ̀ Morrocco ku díẹ̀ kó yẹlé wò ṣugbọn asọ́le ikoọ̀ Senegal, Bounou kò gbà. Ikọ̀ Morrocco tun ní anfààní láti gbá ayò golí wòó ki n gba siọ(Pẹnáritì) sugbọn asọ́le ikọ̀ Senegal tun mu ní ikọ̀ Morrocco àti àwọn ololufẹ rẹ̀ bá kaáwọ́ lórí.

Àsẹ̀yin wà àsẹ̀yìn bọ̀, ní àfikún iṣẹju, ogbontarigi agbábọ́ọ̀lù Sadio Mané fi eyín ẹsẹ̀ gba bóòlù fun Idrissa Gana Gueye ti
Pape Gueye kò ṣè meni kò ṣè méjì sọ bọọlu sì àwọ̀n tààrà ní ayò fi wá yori sí oókan sì odo (1-0). Ibi ti igbiyanju ikọ̀ mejeeji pari sì ní èyí lẹyìn ti wọn ti tiraka láti gbá bóòlù wọlé ara wọn lọ̀tún lósì. Ikọ̀ Senegal gbade idije AFCON ti ọdún 2025 ní ìgbà èkejì nínú ìtàn.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button