Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Yóò borí ogun tó n dojúkọ ètò Ààbò àti ọrọ̀-ajé àwùjọ rẹ̀ -–igbákejì ààrẹ Ọ̀sínbàjò
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Igbákejì ààrẹ, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọjọgbọn Yẹmí Ọ̀sínbàjò ti sọ pé, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò borí ogun tó n dojúkọ ètò ààbò àti ètò-ọrọ̀-ajé, tí gbogbo nǹkan yóò sì gún régé fún àwọn ará ìlú, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà ní ilẹ̀ náà.
Ọjọgbọn Osinbajo ṣalaye eyi, ni ọjọ aiku nibi ayẹyẹ eto idagbere Revd. Dokita Israel Akanji, ti o ṣiṣẹ fun ọdun mejile-logun, gẹgẹ bi Oluṣọ-agutan agba ati Alabojuto Ile ijọsin Baptisti akọkọ,ti Garki.
Osinbajo sọrọ ni ṣoki nibi ayẹyẹ ọhun, ti aarẹ ẹgbẹ Kristiẹni ni Naijiria, Revd Olasupo Ayokunle ati Minisita Ipinlẹ fun eto Ilera, Olorunimbe Mamora, awọn oloye miiran ati awọn oludari Kristiẹni wa nibẹ.
Igbakeji aarẹ gboriyìn fun awọn abuda aarẹ tuntun ọhun, ti o si ṣapejuwe rẹ gege bi onirẹlẹ ati adari ti o ṣee fọkan tan.
Igbakeji aarẹ ki Akanji ku oriire ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun rẹ ti o n bọ lọna, ni ọjọ aje,ọjọ kẹrindin-logun Oṣu Kẹjọ. O gbadura ki ọlọrun tubọ fun ni okun , ọgbọn ti o si tun bẹbe fun ojurere ati ibukun Ọlọrun lori gbogbo awọn ọmọ orilẹ -ede Naijiria.
Leave a Reply