Take a fresh look at your lifestyle.

mímójútó ìdàgbàsókè ohun amáyédẹrùn àwọn òsìsẹ́ ìjọba ló le gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ ní Nàíjíríà-Ọ̀jọ̀gbọ́n Osinbajo

125

Igbakeji aarẹ orilẹ ede Naijria, ọjọgbọn  Yemi  Osinbajo ti ni eto atunse to mọnyan lori  nipa ìgbáyé-gbádùn awọn osisẹ  ijọba apapọ nikan ló le mú òpin de ba iwa ibajẹ to wọpọ nile isẹ ijọba.

Ọjọgbọn  Osinbajo  sọrọ yii lasiko to n tẹwọgba iwe atunse lori eto ilana awọn osisẹ fun ọdun 2021-2025,ni eyi ti adari osisẹ ijọba apapọ lorilẹ ede Naijria , iyaafin ọmọwe   Folashade Yemi-Esan gbe fun un .

lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni minisita fun eto idajọ lorilẹ ede Naijiria, Abubakar Malami; Minisita fun eto isẹ ati igbanisisẹ, Chris Ngige; Minisita fun eto inawo , iyaafin Zainab Ahmed; Minisita ipinlẹ fun eto isunna ati ilana orilẹ ede Naijiria , ọmọọba  Clem Agba; ati minisita fun eto isẹ ojupopo ati ilé, Abubakar Aliyu, oluranlọwọ  aarẹ lori eto ọrọ̀ ajé, Adeyemi Dipeolu, ati awọn oludari ile-isẹ alaadani .

Ọjọgbọn Osinbajo tun sọ pe “ O daju pe , igbesẹ lati mu atunse ba igbaye-gbadun awọn osisẹ ijọba apapọ jẹ akọkọ iru rẹ̀ lorilẹ ede Naijiria lati bi ọdun ti o ti pẹ  sẹyin ti wọn ti ri iru atunse  bayii.”

“A ri i pe , a tun lee se ohun nla nipa ile gbigbe fun awọn osisẹ ijọba apapọ. A ni ipinnu lati kọ ilé  fun awọn osisẹ ijọba ti o le ni ẹgbẹrun lọ́ọ̀dúnrún nipa eto ile -kikọ fun awọn osisẹ ijọba apapọ.Ile ifowopamọ ti ijọba apapọ (CBN) ti ya igba biliọnu naira sọtọ lati fi pese ile-kikọ fun awọn osisẹ ijọba orilẹ ede Naijria.”

 

Iyaafin Yemi-Esan naa tun sọ pe mimojuto eto igbaye-gbadun awọn osisẹ ijọba ,paapaa julọ nipa owo osù ati ile gbigbe fun awọn osisẹ yoo tun mu  iwuri ba awọn osisẹ ni eyi ti wọn yoo fi lee maa se isẹ́ wọn bi isẹ́ .

Iyaafin Yemi-Esan tẹsiwaju pe  atunse ti wọn n se nile isẹ ijọba apapọ ti jẹ ki  adinku ba iye owó ti ijọba apapọ maa n danu .

Leave A Reply

Your email address will not be published.