Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Yóò borí ogun tó n dojúkọ ètò Ààbò àti ọrọ̀-ajé àwùjọ rẹ̀ -–igbákejì ààrẹ Ọ̀sínbàjò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

64

Igbákejì ààrẹ, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọjọgbọn  Yẹmí Ọ̀sínbàjò ti  sọ pé, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò borí ogun tó n dojúkọ ètò ààbò àti  ètò-ọrọ̀-ajé, tí gbogbo nǹkan yóò sì gún régé fún  àwọn ará ìlú, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà ní ilẹ̀ náà.

Ọjọgbọn Osinbajo ṣalaye eyi, ni ọjọ aiku nibi  ayẹyẹ eto idagbere   Revd. Dokita Israel Akanji, ti o  ṣiṣẹ fun ọdun mejile-logun, gẹgẹ bi Oluṣọ-agutan agba ati  Alabojuto Ile ijọsin Baptisti akọkọ,ti Garki.

Osinbajo sọrọ ni ṣoki nibi ayẹyẹ ọhun, ti aarẹ ẹgbẹ Kristiẹni ni Naijiria, Revd Olasupo Ayokunle ati Minisita  Ipinlẹ fun eto  Ilera, Olorunimbe Mamora, awọn oloye miiran ati awọn oludari Kristiẹni wa nibẹ.

Igbakeji aarẹ gboriyìn fun  awọn abuda  aarẹ tuntun ọhun, ti o si ṣapejuwe rẹ  gege bi onirẹlẹ ati adari ti o ṣee fọkan tan.

Igbakeji aarẹ ki Akanji ku oriire  ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun rẹ ti o n bọ lọna, ni ọjọ aje,ọjọ kẹrindin-logun Oṣu Kẹjọ. O gbadura ki ọlọrun tubọ  fun ni okun , ọgbọn ti  o si tun bẹbe fun ojurere ati ibukun Ọlọrun lori gbogbo awọn ọmọ orilẹ -ede Naijiria.

Leave A Reply

Your email address will not be published.