Ẹ jẹ́ asojú rere lórílẹ́ èdè Nàíjíríà àti ní Afirika lójúnà ìrìn -àjò yín lọ sí Iwọ̀ -oòrùn Áfíríkà-ọgagun Udounwa
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ọgagun Udounwa ti rọ awọn jẹ aṣoju ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria lati jẹ asoju rere orilẹ -ede Naijiria, lakoko irin -ajo wọn lati ni ẹkọ̀ to ye kooro nipa imọ agbegbe ati lori eto aabo ilu.



Irin -ajo ti o bẹrẹ ni ọjọ aiku, ọjọ kẹjọ, Oṣu Kẹjọ, ti yoo si pari ni, ọjọ kẹrinla, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, jẹ abala pataki kan ninu ilana lori eto aabo Orilẹ -ede, eyi ti o tun jẹ apakan pataki eto ile-ẹkọ naa fun awọn olukopa.
Oludari Irin -ajo Gbogbogbo, ti o tun jẹ alakoso ile-ẹkọ naa, ọgagun Udounwa ti rọ awọn olukopa lati jẹ aṣoju rere ni orilẹ -ede Naijiria ati ti ile-ẹkọ ọhun lakoko irin -ajo naa.
O rọ wọn lati lo anfaani ti wọn ni yii, lati wa imọ kun imọ wọn, lori ibaraẹniṣepọ agbegbe ati eto aabo, nitori pe wọn wulo lati koju ipenija to n dojukọ ilu ati agbegbe wọn.
Leave a Reply