Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jẹ́ asojú rere lórílẹ́ èdè Nàíjíríà àti ní Afirika lójúnà ìrìn -àjò yín lọ sí Iwọ̀ -oòrùn Áfíríkà-ọgagun Udounwa

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

47

Ọgagun Udounwa ti rọ awọn jẹ aṣoju ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria lati jẹ asoju  rere orilẹ -ede Naijiria,  lakoko irin -ajo wọn lati ni ẹkọ̀ to ye kooro nipa imọ agbegbe ati lori eto aabo ilu.

Irin -ajo ti o bẹrẹ ni ọjọ aiku, ọjọ kẹjọ, Oṣu Kẹjọ, ti  yoo si pari ni, ọjọ kẹrinla, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, jẹ abala  pataki  kan ninu ilana  lori eto aabo Orilẹ -ede, eyi ti o tun jẹ apakan  pataki  eto ile-ẹkọ naa fun awọn olukopa.

Oludari Irin -ajo Gbogbogbo, ti o tun jẹ alakoso ile-ẹkọ naa, ọgagun Udounwa ti rọ awọn olukopa lati jẹ aṣoju rere  ni orilẹ -ede Naijiria  ati ti ile-ẹkọ ọhun lakoko irin -ajo naa.

O rọ wọn lati lo anfaani ti wọn ni yii,  lati  wa imọ kun imọ wọn, lori ibaraẹniṣepọ agbegbe ati  eto aabo, nitori pe wọn wulo lati koju ipenija to n dojukọ  ilu ati agbegbe wọn.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.