UNGA 78: Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ akitiyan àgbáyé láti rẹ́yìn ikọ́ àwúgbẹ
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Nàìjíríà, pẹlu awọn orilẹ-ede Ajọ Iṣọkan, Aṣoju ẹgbẹ ara ilu, ati awọn awọn ti o tun nii lọ́kàn, ti fọwọsi ikede lati ṣe agbekalẹ eto láti rẹ́yìn ikọ́ àwúgbẹ (TB) ni kiakia ni ọdun 2030.
Iwe naa ṣalaye erongba tuntun ni ọdun marun ti n bọ, leyi ti titọju ati idaabobo ida aadọrun ninu ọgọrun awọn ti o ni ikọ awugbẹ TB wa lara rẹ, ipese eto anfaani ibaraẹniṣepọ fun awọn ti o ni aarun naa, ati okere ju iwe iyọnda fun Ajẹsara tuntun kan.
TB jẹ ikeji ajakalẹ aarun apaniyan ti n ran jakejado agbaye lẹyin aarun COVID, ti o si ti gbẹmi eniyan to fẹẹ to miliọnu meji ni ọdun 2021 nikan, bi Ajọ to n risi Ilera Agbaye (WHO) ṣe sọ.
Bakannaa, Ajẹsara kan soṣo ti o wa fun ikọ Awugbẹ ti wa lati bii ọgọrun ọdun sẹyin.
Gbogbo awọn orilẹ-ede mejedin-nigba ti o jẹ ti Ajọ naa ati awọn to nii ṣe wa pinnu nibi apejọ pataki naa, lori igbogunti Ikọ Awugbẹ ninu apejọ ile-igbimọ gbogbogboo ti Ajọ Iṣọkan elẹẹkejidin-lọgọrin ti n lọ lọwọ bayii.
Leave a Reply