Take a fresh look at your lifestyle.

Kò sí ẹni tí ó fara pa níbi ilé tí ó dàẃo ní Ìlú Eko- NEMA

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 382

Àjọ tó ń rísí ìṣàkóso pàjáwìrì lórílẹ̀-èdè, NEMA, ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta pé kò sí ẹni tí ó fara pa níbi ilé alájà mẹ́ta tí ó dàẃo ní òpópónà Ikpoh, ní Surulere, ní ìpínlẹ̀ Eko, Iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.

Ọgbeni Ibrahim Farinloye, Alakoso agbegbe fun NEMA, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun News Agency Nàìjíríà, NAN, ní ìlú Èkó.

Ile naa dawo ni deede agogo mẹwaa alẹ, ní ọjọ Ẹti, ni ojule kẹrinla, opopona Ikpoh, Surulere.

Ikan lara awọn olugbe ninu ile naa, ỌgbeniGervase Anyanwu, ti o jẹ oniṣowo, sọ fun NAN pe awọn olugbe toku sa jade ninu ile naa ki o to dawo patapata.

Anyanwu wa sọ pe ki ile naa to dawo, ariwo kan to lagbara wa lati apa kan ile naa.

Kò sí ẹni tí ó fara pa ,” Anyanwu sọ bayii.

Anyanwu sọ pe kiko awọn olugbe ile naa jẹ “Aanu Ọlọrun.”

Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣalaye, awọn olugbe ni opopona ile naa sọ pe ile naa ti fihan pe o ti gbo sara ki o to dawo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button