Babajide Sanwo-Olu ti ìpínlẹ̀ Eko ti buwọ́lu yíyan Ọ̀gbẹ́ni Ọlabọde Agoro gẹ́gẹ́ bíi adarí àwọn òṣìṣẹ́ tuntun ẹlẹ́ẹ̀kejìlé-lógún.
Adarí àwọn òṣìṣẹ́ ti o n lọ bayii, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunola, sọ eyi ninu ifiranṣẹ to fi sita pe yoo bẹrẹ iṣẹ lati ọgbọnjọ, ọṣu kẹsan an.
“ O pa dandan lati mọ pe, adarí àwọn òṣìṣẹ́ tuntun darapọ mọ oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ni ọjọ kinni, oṣu keje 2003 ti o si jẹ pe lati igba naa lo ti n sin ijọba tọkantọkan ki o to gba igbega si ipo Akọwe agba ni ọjọmkẹta, oṣu kẹjọ, 2015.
“Ki wọn to yan si ipo yii, Agoro jẹ Akọwe Agba, ti Lands Bureau,” Muri-Okunola sọ bayii, ti o si wa rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba lati ṣatilẹyin ati fọwọsowọpọ pẹlu adarí àwọn òṣìṣẹ́ tuntun lori iṣagbelarugẹ awọn aṣeyọri ẹni ti o ṣẹṣẹ fipo silẹ.
“Nigba ti o wa n gbadura fun adari awọn osiṣẹ tuntun fun ere to pọ ati aṣeyọri lẹnu iṣẹ, awọn oṣiṣẹ oniṣiro wa rọọ lati ṣakiyesi ifiranṣẹ yii ki o si jẹ ki ó de eti gbogbogboo,” adarí àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń lọ sọ báyìí.
Leave a Reply