Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó kí Aya Ààrẹ kú oríire ọjọ́ ìbí ọdún mẹ́tà-lé-lọ́gọ́ta.

0 212

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ki aya aarẹ, Aṣofin Olurẹmi Tinubu ku oriire ọjọ ibi, ọdun mẹta-le-lọgọta to pe nile-aye.

Oludari Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti o pa a laṣẹ fun Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ lati kọwe ikini-ku-oriire si Obinrin Akọkọ lorilẹ-ede Naijiria yii lorukọ awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin Eko, ṣe apejuwe Aṣofin Olurẹmi Tinubu gẹgẹ bi obinrin rere ti o n fi gbogbo igba fa eniyan mọra. O ni:

“Lati igba ti o ti kọkọ jẹ obinrin akọkọ ni Ipinlẹ Eko ni o ti mu igberu ba Igbimọ Aya awọn Alaṣẹ Ijọba ni Ipinlẹ Eko (COWLSO), eleyii ti wọn mọ riri rẹ titi di oni.

“Ajọ rẹ ti o pe ni ‘New Era Foundation’ ti mu igberu ba igbe-aye ọpọlọpọ awọn eniyan, paapaa opó. Bẹẹ ni o ti fi eyi mu idagbasoke ba eto ẹkọ, nipasẹ idije ‘Spelling Bee’ ti o ti fun ọpọ ọmọde lanfani lati di Gomina Ọjọ kan ni Ipinlẹ Eko.

“Nigba ti o wa ninu Ile Aṣofin-agba naa, o sapa takuntakun fun ilọsiwaju Ipinlẹ Eko, ti awọn ara ipinlẹ yii si mọ riri rẹ.

“Bakan naa gẹgẹ bi Obinrin Akọkọ bayii lorilẹ-ede Naijiria, o ti sa gbogbo ipa lati ṣe iranlọwọ fun awọn eniyan, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ. O tun n ṣe gbogbo eyi laṣeyọri nipasẹ ajọ rẹ, ‘Renewed Hope Initiative’, ati pe iṣẹ akikanju rẹ yii ti ran ọpọlọpọ eniyan lọwọ”

Ṣaaju eyi, Aṣofin Ọmọlara Olumẹgbọn ti o mu aba ikini-ku-oriire yii wa, mọ riri iṣẹ aanu Aṣofin Rẹmi Tinubu, gẹgẹ bi Obinrin Akọkọ ni Ipinlẹ Eko ati gẹgẹ bi Aṣofin-agba nigba naa. O ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi Iya rere, Ẹlẹyinju-aanu, Oloṣelu ati Ọmọ Naijiria Rere.

Aṣofin Joseph Kẹhinde gboriyin fun Aṣofin Tinubu gẹgẹ bi Obinrin to nifẹ opó ati awọn ọmọde pupọ. Aṣofin Olotu Emmanuel gboriyin fun un pe, gbogbo igba ni o fi n ṣe iranlọwọ fun awọn eniyan.

Aṣofin Mosunmọla Ṣangodara ṣapejuwe Aṣofin Tinubu gẹgẹ bi akikanju obinrin ti o ni ibẹru Ọlọrun, ẹni ti o maa n bọwọ fun ẹnikẹni. O ni: “O jẹ ẹni ti awa obinrin yẹ ka fi ṣe awokọṣe, nitori gbogbo igba n Io fi n ṣatilẹyin fun ọkọ rẹ, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button