Take a fresh look at your lifestyle.

Olórí Àwọn Ọmọ-ogún Ṣé Àyẹwò Ìgbàradi Àwọn Ọmọ-ogún Ní Makurdi

0 231

Olórí Ológun (COAS), Lieutenant General Taoreed Lagbaja, tí ṣé àyẹwò àwọn ọmọ-ogún 401 ní Makurdi, Ìpínlẹ̀ Benue, ní ìtèsíwájú ìrìn-àjò àyẹwò rẹ̀ fún Ìgbàradi wọ̀n ní gbogbo àwọn ẹka tí Ile-iṣẹ́ ológun tí Nàìjíríà.

Èyí jẹ́ apakan nínú àwọn ìgbìyànjú rẹ̀ látí tún mú ẹsẹ àwọn ọmọ-ogún múlẹ sí láti ṣé àdínkù gbogbo italaya ààbò ní Orílẹ̀-èdè náà

Nínú ọrọ̀ kàn tí Olùdarí Ibanisọrọ Gbogbo Ọmọ-ogún, Brigadier General Onyema Nwachukwu, sọ pé Olórí Ológun náà ṣé àfihàn ìdùnnú rẹ̀ sí àwọn ọmọ-ogún fún isé takuntakun tí wọ́n ṣé ní ẹ̀kà ààbò orílẹ̀-èdè náà.

General Lagbaja ní Ọjọ́bọ̀, ọgbọn ọjọ́, Oṣù Kọkànlá ọdún 2023, rọ wọ́n látí tẹ̀síwájú lórí ipá wọ́n láti ṣétọ́jú àlàáfíà ní orílẹ̀-èdè náà. O tún rọ̀ wọ́n látí yàgò fún àwọn irúfin lẹ́nu iṣẹ́ .

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button