Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti se àfirinlẹ̀ ìgbáradì ìjọba rẹ̀ láti pèsè omi tí ó mọ́ tóní-tóní ní ìpínlẹ̀ náà.
Sanwo-Olu, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ níbi àpérò ètò ìmọ́tótó omi ẹlẹ́ẹ̀kẹrin irú ‘rẹ̀, ní àyájọ́ Ọjọ́bọ̀, ní erékùsù Victoria, ìlú Èkó. Ó tẹ̀síwájú pé, ìpèsè omi tí ó mọ́ tóní-tóní se pàtàkì fún irúfẹ́ ìlú bí Èkó, nítorí ìdàgbàsókè ti o n waye nibẹ ti àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ síi ní ọjọọjúmọ́.
Gómìnà wòye pé, pẹ̀lú àfojúsùn òǹkà ènìyàn tí yóò tó ogójì mílíọ̀nù ní ọdún 2050, ó se pàtàkì kí ìgbáradì fún ìpèsè omi tí ó dára àti àyíkà tí ó mọ́ ti máa wáyé láti àsìkò yí lọ.
Leave a Reply