Botswana ti gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì sí ààbò ìlera gbogbogbò lẹ́yìn tí àwọn alenulọ́rọ̀ pàtàkì ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìdámọ̀ràn fún ètò Ìdámọ̀ràn Ìlera Orílẹ̀-èdè wọn tí a ṣe láti rí i dájú pé gbogbo ọmọ Motswana ní àǹfààní sí ìtọ́jú ìlera tó rọrùn tí ó sì dára.
Minisita eto Ilera Stephen Modise sọ fun awọn olukopa idanileko ni Gaborone ni ipari ose pe eto ilers abanidofo Apapo, National Health Insurance, NHI jẹ atunṣe pataki ti a pinnu lati koju awọn àlà ti o wa ni eto ilera, pẹlu awọn akoko idaduro pipẹ, paapaa julọ fun awọn ara ilu ti kò ni ìranlọwọ eto ilera.
Minisita naa ṣe akiyesi pe NHI yoo jẹ dandan ṣugbọn yoo gba awọn eto iranlọwọ ilera aladani laaye lati tẹsiwaju ni iṣiṣẹ kẹ̀gbẹ́ kẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
Temitopè Obisèsan