Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n Dánásun Ọkọ̀ Ámbúlànsì Júù Níbi Ìkọ̀lù

150

 

Àwọn ọkọ̀ Ámbúlànsì mẹ́rin tí ó jẹ́ ti àjọ àwùjọ àwọn Júù ní Àríwá ìlú London ni wọ́n ti jó ní alẹ́ ọjọ́ kan nínú ohun tí Adarí ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Keir Starmer, pè ní “ìkọlù ìgbóná tí ó burú jáì tí ó lòdì sí àwọn Júù.”

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ti sọ, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí wọ́n jẹ́ ti Iran, tí wọ́n pè ní Islamic Movement of the People of the Right Hand, sọ pé àwọn lọ wa nidi ọran náà, èyí tó ṣẹlẹ̀ nítòsí sínágọ́gù kan ní Golders Green.

Ẹgbẹ́ náà tún sọ pé àwọn ló ní ipa nínú irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní orile-ede Belgium, Greece àti Netherlands.
Olórí Starmer dá ìkọlù náà lẹ́bi, ó sì fi ìṣọ̀kan hàn sí àwùjọ àwọn Júù.

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ní ìdàgbàsókè nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lòdì sí àwọn Júù láti ọdún 2023. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn tó le jùlọ wáyé ní ọdún 2025 ní Manchester, níbi tí wọ́n ti pa àwọn Júù méjì tí wọ́n jẹ́ olùjọ́sìn nígbà Yom Kippur.

 

 

 

 

Temitopè Obisèsan

Comments are closed.

button