Senegal ti bẹ̀rẹ̀ sí ní múra sílẹ̀ fún ìdíje Ife Eye agbaye Ôdún 2026 pẹ̀lú Idije Ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ̀rẹ́ pẹ̀lú orile-ede Peru àti àwọn aládùúgbò won, Gambia, wọ́n sì dúró pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ògbóǹtarigí agbaboolu tó díje ní ìdíje African Cup of Nations ní orile-ede Morocco.
Ṣùgbọ́n, Olùkọ́ni Bouna Papa Thiaw ni igbà àkọkọ ti pè Nobel Mendy láti ẹgbẹ́ Rayo Vallecano ti Spain àti Mamadou Diakhon tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù fun Kílọ̀bù Brugge ni Belgium.
Ikọ̀ Senegal yóò kọkọ koju ìkọ ti Peru ni papa isere Stade de France ni Paris ni ojó Abameta kó tọ lọ koju ikọ̀ Gambia ni ọjọ kọkànlelélọ́gbọ̀n osù kéta ni ile wọn ni Dakar.
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ti akoni-moogba fẹ lò ni wonyi:
Àwọn asọ́le: Mory Diaw (Le Havre, France), Yehvann Diouf (Nice, France), Edouard Mendy (Al Ahli, Saudi Arabia)
Àwọn Adeyinmu: Krepin Diatta (Monaco, France), El Hadji Malik Diouf (West Ham United, England), Ismail Jakobs (Galatasaray, Turkey), Kalidou Koulibaly (Al Hilal, Saudi Arabia), Antoine Mendy (Nice, France), Nobel Mendy (Rayo Vallecano, Spain), Moussa Niakhaté (Olympique Lyonnais, France), Mamadou Sarr (Chelsea, England), Abdoulaye Seck (Maccabi Haifa, Israel)
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ni ipò aarin: Lamine Camara (Monaco, France), Pathe Ciss (Rayo Vallecano, Spain), Habib Diarra (Sunderland, England), Idrissa Gana Gueye (Everton, England), Pape Gueye (Villarreal, Spain), Pape Matar Sarr (Tottenham Hotspur, England)
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ni ipò iwaju: Boulaye Dia (Lazio, Italy), Habib Diallo (Metz, France), Assane Diao (Como, Italy), Bamba Dieng (Lorient, France), Nicolas Jackson (Bayern Munich, Germany), Sadio Mane (Al Nassr), Ibrahim Mbaye (Paris St Germain, France), Cherif Ndiaye (Samsunspor, Turkey), Iliman Ndiaye (Everton, England), Ismaïla Sarr (Crystal Palace, England).
Temitọ́pè Òbísẹ̀san