Ìjọba ìpínlẹ̀ Nasarawa ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹgbẹ́ àwọn Dókítà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera ní ìpínlẹ̀ náà láti Sẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gùnlé, lójúnà àti dóòlà ẹ̀mí àwọn aláàárẹ̀ tí ó wà ní ilé ìwòsàn gbogbo jákè-jádò ìpínlẹ̀ náà.
Tí a kò bá gbàgbé, Dókítà Peter Attah ti o jẹ alaga ẹgbẹ awọn Dokita fi àbájáde ìpàdé ẹgbẹ́ náà léde ní àyájọ́ Ọjọ́bọ̀, lati gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ márùn-ún. Ìyanṣẹ́lódì náà bẹ̀rẹ̀ ní àyájọ́ Ọjọ́bọ̀ ti yóò sì parí ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹẹ̀wá osù keje.
Ìgbésẹ̀ náà wáyé láti jẹ́ kí ìjọba mú ìròńgbà àti àdéhùn ìpèsè oun ìgbáyégbádùn fún àwọn Dokita eleto ilera sẹ.
Leave a Reply