Àjọ Ọlọ́pàá ẹka ti ìpínlẹ̀ Kano ti fi ìgbáradì rẹ̀ lédè láti palẹ̀ àwọn jàǹdùkú mọ́ àti sísàfọ̀mọ́ ìpínlẹ̀ náà kúrò níbi àwọn ìwà burúkú inírú ‘rú.
Kọmísọ́nà àjọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà, Mohammad Hussaini Gumel ni ó so ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó n se àfihàn àwọn òbìlẹ̀jẹ́ tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún látàrí oríṣìírìṣí ìwà ìbàjẹ́.
Gẹ́gẹ́ bi o se sọ, ajọ naa ti nawọ́ alaafia lati fi ọ̀rọ̀-jomitoro-ọ̀rọ̀ pẹ̀lú awọn oníwà janduku mẹ́rìndínlógún ni ipinlẹ naa, fun àsọyépọ̀ lati fi òpin si rúkè-rúdò ti o n waye. Ìrètí wa pe igbesẹ naa yoo so eso rere.
Leave a Reply