Take a fresh look at your lifestyle.

Regina Daniels Se Ayẹyẹ Ìyànsípò Ọkọ Rẹ̀ Padà Sí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin

0 228

Gbajú-gbajà òsèré, Regina Daniels, ìyàwó onísòwò ńlá, Ned Nwoko ti se ayẹyẹ ìyànsípò ọkọ rẹ̀ padà sí ilè ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ní ìlú Abuja.

 

Wọ́n búra fún Nwoko ni ọjọ kẹtala osu kẹfà ọdun 2023 láti darapọ̀ mọ́ awọn akẹgbẹ́ rẹ ni ile igbimọ asofin ẹlẹ́ẹ̀kẹẹ̀wá.

 

Nínú àwọ̀rán fídíò kan ti o jade lori ẹrọ ayélujára ni àyájọ́ Ọjọ́bọ̀, Nwoko ẹni ti o sojú ẹkùn Anioma, àréwá ìpínlẹ̀ Delta, ni o n ki awọn akẹgbẹ rẹ ni gbọ̀ngàn ilé asòfin.

 

Regina wá fi ìgbàgbọ́ hàn pé, ọkọ òun kójú òsùwọ̀n láti se iṣẹ́ tí ó wà ní iwájú rẹ bí ó ti se yẹ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button