Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà Rọ́ Àwọn Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ Láti Bọ̀wọ̀ Fún Àṣẹ Ilé-ẹjọ́

0 282

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ké sí àwọn àjọ òṣìṣẹ́ láti má ṣe gúnlé yanṣẹlodi, kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àṣẹ tí Ilé Ẹjọ́ pá wọ́n ọjọ́ karún-ùn oṣù kẹfà.

Ilé-ẹjọ́ tí pàṣẹ fún Ìgbìmọ̀ àwọn Òṣìṣẹ́ (NLC) àtí (TUC) láti má gúnlè iyanṣẹlodi latari yíyọ ìrànwọ́ owó orí èpò àtí àwọn òun mìíràn.

Èyí wá nínú lẹta tí Agbẹjọro Gbogbogbò tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Mínísítà fún Ìdájọ́, Lateef Fagbemi sí àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́.

Agbẹjọro àgbà náà pá arọwa fún agbẹjọro àwọn Òṣìṣẹ́ Ọ̀gbẹ́ni Femi Falana láti rọ àwọn oníbàárà rẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún àṣẹ ilé-ẹjọ́, kí wọ́n sì fi ayé gbá idunadura láàrin àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àtí ìjọba.

Ààrẹ Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ (NLC), Joe Ajaero, àtí (TUC), Festus Osifo, tí gbá láti gúnlè iyanṣẹlodi ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọ 26th, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹwàá, ọdún 2023.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button