Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Kẹ́dùn Ikú Ọba Àwọn Ẹ̀yà Ìgbò Ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

0 322

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kẹ́dùn ikú Eze Ndigbo Ilẹ Ìbàdàn, Omowe Alex Anozie tíì ṣe Oba àwọn ẹ̀yà Ìgbò to wa ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, to sì ṣe àpèjúwe ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ohun tó dunni jọjọ.

Gómìnà, ẹni tó ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn yìí gẹ́gẹ́ bi o ṣe jẹyọ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ Akọwe ìròyìn rẹ̀ Suleimon Olanrewaju to fi ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lo fi iku olóògbé náà wẹ àdánù nlá.

Gómìnà Makinde wá fí Olóògbé Anozie wé Olórí tó lààmì-laaka àti ẹni tó ní ìgbàgbọ́ tó sì ṣíṣe fún àlàáfíà àti ìlọ́rọ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀.

Bákan náà ni Gómìnà tún kẹ́dùn pẹ̀lú ìdílé olóògbé náà, Olúbàdàn Ilẹ Ìbàdàn, Ọba Lekan Balogun àti gbogbo ẹ̀yà Ìgbò tó wà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, O wa gbàdúrà kí Ọlọrun tẹ Olóògbé Anozie sí afẹ́fẹ́ rere.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button