Ẹ Dá Gbogbo Síìmù Tí Wọn Kò So Pọ̀ Pẹ̀lú Nọ́ḿbà Ìdánimọ̀ Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà (NIN) Dúró
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti pàṣẹ ìdádúró gbogbo àwọn siimu ti wọn ko ni nọ́mbà ìdánimọ̀ orílẹ̀-èdè (NIN).
Asẹ yi jade lẹyin ti gbendeke ti ijọba fi silẹ fun iforukọsile fun nọmba idanimọ Orilẹ-ede Naijiria (NIN) pari ni ọjọ kọkanllelọgbọn Oṣu Kẹta 2022.
Asẹ yi jade ninu atẹjade kan ti Igbimọ awọn Minisita Lori eto isopọ SIM / NIN gbe jade ni ọjọ kẹrin, Oṣu Kẹta 2022 ti Oludari, Awujọ, Igbimọ Ibaraẹnisọrọ Naijiria (NCC), Dokita Ikechukwu Adinde ati Alakoso, Igbimọ Ibaraẹnisọrọ, National Identity Management Commission (NIMC), Kayode Adegoke fi ọwọ si.
Leave a Reply