Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, paapaa awọn musulumi lati fọkan jin, pẹlu alekun ifẹ ati igbọran si gbogbo ilana Ọlọrun Allah paapaa ninu oṣu alapọnle mimọ tẹsin isilaamu ti a wa yii.
Aṣofin Ọbasa sọrọ iṣiti yii ninu atẹjade kan lati ile-iṣẹ alukoro rẹ, nibi ti o ti ki awọn musulumi ku oriire aawe Ramadan ti ọdun 2022 yii ti o ṣoju ẹmi wọn.
Aṣofin Ọbasa sọ pe anfani nla ni osu mimo yii lati fi ri ibukun Ọlọrun Allah gba “lasiko yii ti a n tẹle ilana ti o fi lelẹ fun wa”
O tun rọ awọn musulumi kaakiri orilẹ-ede yii lati fi alaafia mulẹ gẹgẹ bi ohun rere fun orilẹ-ede Naijiria. O ni:
“Mo ki gbogbo wa ti a jẹ musulumi ododo fun anfani ati ore-ofe ti a tun ni, pe aawe Ramadan tọdun yii ṣoju ẹmi wa. Gẹgẹ bi musulumi, a ni lati mọ pe asiko ifọkan jin, oṣu mimọ ati asiko gbibga adura ni kikun si Ọlọrun Allah niyi, tii ṣe Ọkan ṣoṣo lanaa, Ọkan ṣoṣo loni, ti yoo si maa bẹ titi aye.
“Ẹ jẹ ki a fi ifẹ pipe han sira wa ni asiko yii, paapaa ju bi a ti n ṣe tẹlẹ lo, ti a si gbọdọ maa ṣe bẹẹ ni gbogbo ọjọ aye wa. Eleyii ni ohun ti Ọlọrun n beere lọwọ wa, ti a gbọdọ maa ṣe.
O tun gbadura pe “Ki Ọlọrun Allah gba gbogbo adura wa, ki O si fi oju aanu ati oju rere re wo wa. Amin.
Ẹ ku oṣu Ramadan.”
Leave a Reply