Amòfin Sarafadeen Abiodun Allí tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló jáwé olubori ní ẹkùn ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́ gẹgẹ bí o ti farahàn nínú èsì ìdìbò Aṣojú-Ṣòfin tó wáyé ni ọjọ́ Karundinlọgbọn oṣù yìí.
Amòfin Alli ti o dije du ipò Aṣoju Ẹkùn Ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni àjọ eleto Ìdìbò, INEC ti kede pe o jáwé olubori.
Nígbà tí Sarafadeen Alli tí ẹgbẹ òṣèlú APC ní ibo 111,513, nígbà tí àwọn tí o figagbaga pẹlu rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Olasunkanmi Tegbe ni ibo 92,481; Kolapo Koka-Daisi ẹgbẹ òṣèlú ‘Accord’ ni ibo 33,641; tí Oladimeji Theophilus ẹgbẹ òṣèlú LP ni ibo 22,657.
Nígbà tí o kéde èsì ìdìbò náà ní ilé ẹkọ Gírámà Ikolaba ní Ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlè Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹni tí o ṣe akojọpọ èsì ìdìbò fún Ẹkun ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́, Ọjọgbọn Wole Olatokun ti ilé ẹkọ gíga Fafiti Ìbàdàn sàlàyé wí pé Sarafadeen Alli tí yege pẹ̀lú èsì ìdìbò náà ní ìbámu pẹlu òfin, tí o sì kéde rẹ gẹgẹ bí olubori tí yóò dojú ẹkùn ìdìbò náà.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply