Take a fresh look at your lifestyle.

Egbẹ́ Òṣèlú PDP Jáwé Olúborí Ní Ọ̀nà Méjì Nínú Ìbò Ipò Sẹ́nétọ̀ Ti Ìpínlẹ̀ Adamawa

0 286

Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP ti Jáwé Olúborí ní ọ̀nà méjì nínú Ìbò Sẹ́nétọ̀ ti Ìpínlẹ̀ Adamawa ti Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC sì Jáwé Olúborí ní ọ̀nà kan soso.

Ní Ẹkùn Gúsù Adamawa, Sẹ́nétọ̀ tó wà lórí Oyè, Benus Yauro náà ló tún wọlé.

Bákan náà, ní ẹkùn Àríwá, ọmọ ẹgbẹ́ APC, Ishaku Elisha ló jáwé Olúborí. Òun náà ló ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ bíi Sẹ́nétọ̀ ní agbègbè náà.

Síbẹ̀síbẹ̀, Sẹ́nétọ̀ tuntun fojúhàn ní àárín gbùngbùn Ìpínlẹ̀ Adamawa. Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó wà lórí oyè, Ògbẹ́ni Aminu Abbas ti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lo já ewé Olúborí. Ó borí Ọ̀gbẹni Abdulaziz Yako, Sẹ́nétọ̀ tẹ́lẹ̀ láti ìhà náà.

Ìròyìn lékununréré nipa abajade esi ibo n bó laipé.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button