Akojọpọ èsì ìdìbò gbogboògbò ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi hàn wí pé, ninu àwọn ẹgbẹ òṣèlú Mejidinlogun ti wọn figagbága láti du ipò Ààrẹ, ẹgbẹ òṣèlú APC ló jáwé Olubori pẹlu ìbò 449,884.
Ẹni tíì ṣe Adele Ọgá Àgbà Ile Ẹkọ Fafiti FUNAAB ni ìlú Abeokuta, Ọjọgbọn Babátúndé tó ṣe akojọpọ èsì ìbò Ààrẹ fún ìjọba ìbílẹ̀ Metalelọgbọn tó wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló kéde èsì ìbò náà ni Gbọngan Mutiu Agboke ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ Ketadinlọgbọn oṣù Kejì Ọdún yìí nibi tí o ti kéde ẹgbẹ òṣèlú APC gẹ́gẹ́ bí Olubori nínú ètò ìdìbò gbogboògbò to wáyé ni ọjọ Karundinlọgbọn oṣù yìí.
Nígbà tí Asíwájú Ahmed Tinubu to dije labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC borí pẹlu ìbò 449,884; ẹgbẹ òṣèlú LP tí Peter Obi ti dije rí ìbò 99,110; ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti Alhaji Atiku Abubakar ti dije ní ìbò 182,977.
Èsì ìdìbò náà tún fi hàn wí pé, gbogbo oludibo tó forúkọ sílẹ̀ ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ (TRV) jẹ: 3,237,310; ti gbogbo oludibo tó ṣe ayẹwo orukọ wọn (AV) jẹ, 854,439; iye ibo tí oludibo dì lónà ẹtọ (TVV) jẹ, 809,485; iye ìbò ti àwọn oludibo dì ní ònà àìtó (RV) jẹ, 42,471; nígbà tí apapọ ìbò ti wọ́n dì (TVC) sì jẹ́ 851,956.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply