Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí pàdà sí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹyìn tó tí kópa nínú ìpàdé G20 tí wọ́n pé ní ‘Compact with Africa (CwA)’ tí Alákóso Ìlú Germany Olaf Scholz gbàlejò rẹ̀.
Ọkọ Òfurufú tí Ààrẹ balẹ̀ ní pápá ọkọ̀ Òfurufú ‘Nnamdi Azikwe ní ago mẹjọ alẹ́ (8pm) Ọjọ́rú, bí Mínísítà fún Olú-ìlú Nàìjíríà, Nyesom Wike ṣé lọ́ pàdé rẹ̀ pẹ̀lú Alága tí ẹgbẹ́ òṣèlú ‘All Progressives Congress (APC)’, Abdullahi Ganduje; àti Olórí àwọn Òṣìṣẹ́ Ààrẹ, Femi Gbajabiamila.
President @officialABAT returns after participation at the G20 Compact with Africa Economic Conference in Berlin, Germany#PBAT pic.twitter.com/5imPqPPr4Y
— Presidency Nigeria (@NGRPresident) November 22, 2023
Ààrẹ Tinubu kúrò ní Abuja ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú lọ sí Berlin, níbí àpéjọ G20 CwA tó wáyé ní àkókò kànnà pẹlú àpéjọ òwò láàrin Germany àti Nàìjíríà ẹlẹkẹwaa ní JW Marriott Hotel.
Tún ká nípa:Ọkọ̀ Òfurufú Ààrẹ Nàìjíríà Balẹ̀ Ní Germany Látí Kópa Nínú Àpéjọ G20 Pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀
Làkókò àpéjọ náà, Ààrẹ Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn olórí orílẹ̀-èdè mìíràn àti ìjọba tí àwọn orílẹ̀-èdè ọmọ ẹgbẹ́ CwA, àwọn alájọṣiṣẹ́pọ̀ ìṣòwò, àti àwọn olórí ilé-iṣẹ́ nlá nlá ní àgbáyé látí jíròrò àwọn ìlànà ìlọsíwájú ètò ọrọ̀ ajé àti láti mú ìṣòwò tí Nàìjíríà dára sí.
Làkókò Àpéjọ Ìṣòwò Orílẹ̀-èdè Germany, Nàìjíríà ní anfààní pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ òye méjì kàn tí Germany. Ọkàn fún tó tó ẹdẹgbẹta mílíọ̀nù dọla ($500m) tí èkejì sí jẹ́ fún ìpèsè gaasi láti Nàìjíríà lọ́ sí Germany.
Leave a Reply