Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Nàìjíríà Fọwọ́sí Ìlànà Ìnáwó Alábọdé 2024 – 2026

0 229

Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà tí fọwọ́sí Ìlànà Ìnáwó Alábọdé 2024-2026 àti Ìwé Ìlànà Ìnáwó (MTEF/FSP).

Ìfọwọ́sí náà ló wáyé lẹyìn ìgbéjáde àbọ̀ tí Ìgbìmọ̀ Àkójọpọ̀ Aṣojú Alàgbà kàn, tí Sani Musa jẹ́ alága rẹ̀, lẹyìn àyẹwò fínífíní tí Ilé-ìgbìmọ̀ náà ṣé lórí àwọn ìṣirò tí àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ (Ministries), àwọn ẹ̀kà (Departments) àti àwọn ilé-iṣẹ́ kerejekereje tí ìjọba (MDAs) nínú ìwé ìnáwó náà.

Ilé-ìgbìmọ̀ náà wá fọwọ́sí èrò ẹ̀yawó Tiriliọn mẹ́jọ dín díẹ̀ Náírà (N7.8trilion) fún ọdún 2024 àti àfikún Tiriliọn mẹ́san Náírà (N9 trillion), tí ìnáwó àpapọ̀ tí ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí jẹ́ Tiriliọn mẹ́rin dín lọgbọ́n Náírà (N26 trillion) fún ọdún 2024.

Ààrẹ Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà, Godswill Akpabio, lẹyìn ijiroro tó yẹ́ lórí ìwé-àṣẹ náà fọwọ́sí ìwé-àṣẹ ìnáwó náà pèlú ìbo òun, tí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ sí ṣé àtìlẹ́yìn rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button