COEASU gbóríyìn fún ààrẹ Tinubu fún ìdádúró ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn ún
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ni ti ilé-ìwé olùkọ́ni, COEASU, ti gbóríyìn fún ààrẹ, Bọla Ahmed Tinubu fún bí ó ṣe lo ọgbọ́n tí ó sì dá ìlànà tí ó ní kí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lórílẹ̀-èdè máa san ìdá ogójì nínú ìdá ọgọ́rùn ún owó tí wọ́n bá rí sí àpò ìjọba àpapọ̀.
Eyi wa ninu alaye kan ti aarẹ apapọ COEASU, Dokita Smart Olugbeko fi sita.
Alaye naa sọ pe ẹgbẹ naa ti ri ijọba to ni fẹran isọkan ati ọna orisirisi lati ṣe atunṣe nipasẹ igbesẹ ti ko ni ipalara.
Ni bayii, ẹgbẹ naa wa rọ aarẹ lati dasi ọrọ ninawo lori awọn ile iwe olukọni ati awọn ile-ẹkọ giga toku lorile-ede.
Ẹgbẹ naa tun wa mẹnu ba awọn ọrọ pataki miiran ti o tun nilo agbeyẹwo bii (IPPIS), leyi ti o jẹ ijẹlẹsẹ fun ọpọlọpọ eto ni awọn ile-ekọ giga.
Leave a Reply