Olùdíje fún ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Kàdúná ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Sẹnetọ Uba Sani ti yan igbákejì Gómìnà Nasiru El-Rufai, Dokita Hadiza Balarabe gẹ́gẹ́ bi olùdíje fún ìbò gómìnà tó ń bọ̀ lọ́dún 2023 ní ìpínlẹ̀ náà.
Alagba Sani sọ pe, ipinnu naa waye lẹyin awọn ifikunlukun pẹlu awọn ti o ṣe pataki ni Ipinlẹ naa.
Aṣofin naa sọ pe, yiyan Hadiza ni ṣe pẹlu awọn isẹ ribiribi rẹ si ipinlẹ naa, ati awọn aṣeyọri pataki ti iṣakoso El-Rufai ti ṣe ni awọn amayedẹrun ati idagbasoke ọmọniyan.
O ṣapejuwe Hadiza gẹgẹ bi enikan ti o ti ṣe iṣe takuntakun, lasiko,ti o ni ifarasin ati ẹmi ajọṣepọ ninu ṣiṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bi Igbakeji Gomina, eleyii ti o je ki awon ti ọrọ kan ṣe ni Pataki lati yan an nipinlẹ naa.
Leave a Reply