Take a fresh look at your lifestyle.

Tunisia sọ àwọn gbajúgbajà akọ̀ròyìn méjì sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta ààbọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

248

Ilé ejọ́ Tunisia dá ẹjọ́ tí ó sì sọ àwọn gbajúgbajà akọ̀ròyìn méjì sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta ààbọ̀ lórí ẹ̀sùn yíyọ́ owó orí sílẹ̀, tí ìkan lára ẹbì sọ pé ìgbẹ̀san ìjábọ̀ tí wọn ń ṣe ni.

Awọn akọroyin naa, Bohran Bssaies ati Mourad Zghidi, ṣiṣẹ fun ile iṣẹ asọrọ magbesi orilẹ-ede naa, IFM ti wọn si ti sọwọn sẹwọn lati 2024, lakọọkọ, fun oṣu mẹjọ lẹyin ti wọn fi ẹsun ipolongo iroyin ti ko ni otitọ ninu ati fifi abuku kan Aarẹ, lẹyin naa atimọle igbẹjọ lori ọrọ owo ori.

Aarẹ Kais Saied kọ ẹsun wipe oun to fun awọn akọroyin lominira jalẹ.

Maryem Zghidi, aburo Zghidi, ṣalaye pe atimọle yii ya ẹbi lẹnu, ti o si ṣapejuwe ẹsun naa pe kolẹsẹ nilẹ ati pe igbẹsan fun ominira ominira to ni ni.

 “Idajọ yii jẹ ikoju akọroyin ati ominira sisọ tẹnu ẹni”, o sọ bayi fun Reuters. Wọn fẹ pa Mourad lẹnu mọ, ṣugbọn a ko ni dakẹ.”

Awọn ẹbi awọn akọroyin naa le pẹjọ ko tẹmi lọrun.

Awọn alatako ni ijọba ti n finna mọ awọn adari alatako, awọn akọroyin, ati agbẹnusọ fun ara ilu lati igba ti Saied ti n ṣejọba pẹlu ipa ni 2021.

 

 

Comments are closed.

button