Ìjọba Ìpínle Plateau tí tún séde fún wákàtí mẹ́rìnlé-lógún, léléyìí tí ó ti juwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Jos North, níbi lààsìgbó kan tó wáyé nípasẹ̀ ìkọlù Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ abúlé Yelwa Zangam,tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn, tí àwọn òpọ̀lọpọ̀ dúkìá sì run.
Gẹgẹ bi gomina Simon Lalong ṣe sọ, isede wakati mẹrinle-logun naa yoo bẹrẹ lati agogo mẹrin irọlẹ, loni Ọjọbọ ,ọjọ kẹẹdọgbọn Oṣu Kẹjọ ọdun 2021, titi di akiyesi siwaju.
Ipinnu pataki yii n tẹsiwaju nitori bi emi awọn eniyan ati dukia laarin Agbegbe Ijọba ibilẹ ati lati yago fun irufin ati aṣẹ. Yoo tun jẹ ki awọn ile -iṣẹ aabo ran awọn ọmọ ogun lọ ni sibẹ lasiko lati pese aabo ti wiwa awọn oniṣẹ ibi labule naa yoo si tẹsiwaju.
Gomina naa wa rawọ ẹbẹ si awọn ara ilu Jos North, lati fọwọsowọpọ pẹlu Ijọba nipa titẹle isede wakati mẹrinle-logun naa, ti o bẹrẹ ni agogo mẹrin irọlẹ, ọjọ kẹẹdọgbọn, Oṣu Kẹjọ ọdun 2021, nitori wọn ti paṣẹ fun awọn ile-iṣẹ eto aabo lati rii daju pe wọn mu awọn ti o ba rufin naa.
Leave a Reply