Take a fresh look at your lifestyle.

Ìkọ́lú àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ààbò NDA Yóò pèwón níjà – Ààrẹ Buhari

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

119

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí sọ pé,àjálù tí ó kọlu ilé -ẹ̀kọ́ gíga Ìdáábòbò

Nàìjíríà (NDA) ní ọjọ́ ìṣẹ́gun,kò yẹ kí wọn jẹ́ kí ó dẹ́rùbà ìgboyà wọn, bí kò ṣe  pé, kí wọn ri bíi ìpeni níjà láti fi  òpin sí ìwà ọ̀daràn ní orílẹ̀ -èdè.

O sọ pe  ikọlu naa, eyiti o yori si ipadanu ẹmi, wa ni akoko  ti ologun ti ni ki  awọn alatako, awọn onijagidijagan, awọn ajinigbe, ati awọn iru iwa ọdaràn miiran jawọ ninu iṣẹ aburu wọn.

Nigbati o n ṣekẹdun pẹlu awọn idile ti o padanu awọn ololufẹ wọn, o  gbadura pe ki  Ọlọrun  tù wọn ninu, Aarẹ Buhari bura pe,awọn oloogbe naa ko ni ku lasan,wọn yoo fi imu gbogbo awọn to ba wa nidi iwa aburu naa danrin, nitori pe ẹlẹṣẹ kan ko ni lọ laijiya, ti eyi yoo si jẹ igbesẹ lati fọ orilẹ -ede  mọ nikẹhin .

Aarẹ dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ orilẹ -ede Naijiria ti o mọyì ati riri  akitiyan  ologun, ti o si rọ awọn ti n ṣe oṣelu onikorira pẹlu iwa ibajẹ  lati yago , o pe sọ pe ,ohun ti ko dara ko dara,  akoko yi ni o yẹ ki gbogbo awọn olufẹ orilẹ -ede ati awọn eniyan rere  ṣe atilẹyin ati iwuri fun awọn ti o wa ni iwaju ogun.

Leave A Reply

Your email address will not be published.