Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Plateau,Jos Tún ti séde

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

105

Ìjọba Ìpínle Plateau tí tún séde fún wákàtí mẹ́rìnlé-lógún, léléyìí tí ó ti juwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní  Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Jos North, níbi lààsìgbó kan tó wáyé nípasẹ̀ ìkọlù   Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ abúlé Yelwa Zangam,tí ọ̀pọ̀lọpọ̀  ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn, tí àwọn òpọ̀lọpọ̀ dúkìá sì run.
Gẹgẹ bi gomina Simon Lalong ṣe sọ, isede wakati mẹrinle-logun naa yoo bẹrẹ  lati agogo mẹrin irọlẹ, loni Ọjọbọ ,ọjọ kẹẹdọgbọn Oṣu Kẹjọ ọdun 2021, titi di akiyesi siwaju.

Ipinnu pataki yii n tẹsiwaju nitori bi emi awọn eniyan ati dukia   laarin Agbegbe Ijọba ibilẹ  ati  lati yago fun irufin  ati aṣẹ. Yoo tun jẹ ki awọn ile -iṣẹ aabo ran awọn ọmọ ogun  lọ ni sibẹ lasiko  lati pese aabo ti wiwa awọn oniṣẹ ibi labule naa yoo si tẹsiwaju.

Gomina naa wa rawọ ẹbẹ si  awọn ara ilu Jos North, lati fọwọsowọpọ pẹlu Ijọba nipa titẹle  isede  wakati mẹrinle-logun naa, ti o bẹrẹ ni agogo mẹrin irọlẹ, ọjọ kẹẹdọgbọn, Oṣu Kẹjọ ọdun 2021, nitori wọn ti paṣẹ fun awọn ile-iṣẹ eto aabo lati rii daju pe wọn mu awọn ti o ba  rufin naa.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.