Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùndínláàdọ́rùn ún ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kúrò ní ìpínlẹ̀ Plateau

Abiọla Ọlọwẹ

126

Ìjọba  ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àkóso gomina Seyi Makinde ti kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí í se ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ó tó márùndínláàdọ́rùn ún kúrò ni ìpínlẹ̀ Plateau látàri ́rògbòdìyàn tó ń sẹlẹ̀ níbẹ̀.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin fun gomina, ọgbẹni Taiwo Adisa fi sita lo sọ ọ di mimọ pe, Gomina Seyi Makinde lo paa lasẹ fun amugbalẹgbẹ pataki rẹ lori ọ̀rọ̀ akẹkọ̀, Ogbeni Victor Olojede lati saaju ikọ̀ ti o lọ ko àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọhun kuro ni ilu Jos.

 

Olori awọn osisẹ gomina Seyi Makinde, Hon Segun Ogunwuyi ti o gba ẹnu gomina sọrọ wa fi da àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọhun loju pe ijoba ipinle Oyo yoo se gbogbo ohun to wa ni ikawọ re lati daabo bo ẹ̀mí ati dukia gbogbo ọmọ bibi ati olugbe ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ marundinladorun ọhun ni ijoba ipinle Oyo fi oko nla “Oyo State Pacesetter Transport Company” ko wa si Ile isẹ ijọba to kalẹ si agbegbe Agodi ni ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria, ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọhun si fi idunnu wọn han  nigba ti wọn dupe lọwọ ijọba fun igbẹse akin ti wọn gbe lati doola ẹmi wọn.

Ninu ọrọ rẹ, amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori ọrọ akẹkọọ, Victor Olojede to se kokari bi wọn se lọ ko àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọhun kuro ni ilu Jos ,lu gomina Seyi Makinde lọgọ ẹnu fun bi o se jẹ ki o rọrùn lati ko àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọhun kuro. O wa tun dupẹ lọwọ gomina fun ẹ̀mí ifọkansin rẹ eleyi to farahan ninu igbesẹ yii, ti o si fi kun pe, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ naa mọ ọn  loore.

 

Bakan naa ni asiwaju awon akeko ohun ti o tun jẹ Aarẹ “National Oduduwa Students Association” eka ti Unifasiti Jos, Kolawole Paul sapejuwe gomina Seyi Makinde gẹgẹ bi olori to se fọkantan to ko ni gba ki iya jẹ awọn to n sakoso le lori.

Leave A Reply

Your email address will not be published.