Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí wà ní ìpàdé báyìí pẹ̀lú àwọn alákóso ètò Ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ọgá àgbà ológun, General Lucky Irabor, lé iwájú, ní Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ, Abuja.
Ọgágún náà ló ṣíwájú fún àwọn ọgá àgbà Ilé-iṣẹ́ Ààbò mìíràn bíi Ọgá àgbà àwọn ọmọ ogún, Lt. Gen Farouk Yahaya; Olórí ọmọ ogún ojú-omí, Vice Admiral Awwal Gambo; Ọgá àgbà àwọn ọmọ ogún Òfurufú, Air Marshal Isiaka Amao àtí Ọgá àgbà fún àwọn Ọlọ́pàá, Usman Alkali Baba.
Àwọn mìíràn ní Olùdarí Gbogbogbò Department of State Service (DSS), Yusuf Bichi; Olùdarí Gbogbogbò tí National Intelligence Agency (NIA), Ahmed Rufai Abubakar.
Ìpàdé tó ń lọ́ lọ́wọ́ yìí jẹ́ ifọrọwerọ àkọkọ́ tí Ààrẹ Tinubu pẹ̀lú àwọn olórí ètò ààbò àti òye lorílẹ̀-èdè yìí láti ìgbà tí o tí gbà ọ̀pá àṣẹ lọjọ́ Aje, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n Oṣù Karùn-ún, ọdún 2023.
Ọ̀RỌ̀ ÀÀRẸ BOLA TINUBU: ÀYÍPADÀ TUNTUN TI DÉ BÁ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÍJÍRÍÀ
Ààrẹ tí pàdé pẹ̀lú Alága tí Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), Abdulrasheed Bawa, ní ilé-iṣẹ́ Ààrẹ, ní Ọjọ́rú.
Leave a Reply