Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀RỌ̀ ÀÀRẸ BOLA TINUBU: ÀYÍPADÀ TUNTUN TI DÉ BÁ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÍJÍRÍÀ

George Oláyinká Akíntọ́lá

0 254

Ẹ̀yin ènìyàn mi lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà,

Mo dúró sí wájú yin lónìí, Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, Ọṣụ̀ Karùn-ún, Ọdún 2023 láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí ẹ fi rán mi. Ìfẹ́ tí mọ ní sí orílẹ̀-èdè yìí dúró digbí. Ìgbàgbọ́ mìi nínú yín ṣi gbópọn. Mo mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí agbára ènìyàn ò ká.

Ọjọ́ ayọ̀, Ìdùnú, Ọjọ́ tó kún fún ìkíni kuú oríire fún orílẹ̀-èdè wa lònìí jẹ́.

Gẹ́gẹ́ Bi orílẹ̀-èdè a ti pinnu fún ìgbà pípẹ́ láti tayọ ju bó ṣe wà yìí lọ, láti mú ìrètí wa wá sí ìmúṣẹ, oun tí ó yẹ ká bira wa ni pé, ṣe ka máa bá iṣẹ́ dáradára wa lọ, kí á jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ kọ́ orílẹ̀-èdè tó yanrantí

Ìdáhùn mi sí ìbéèrè yìí ni pé, A jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ga gan asì gbalẹ̀ gidi gan, kò ní dára kí a ma jara wa lólò ọjọ́ ọ̀la wa tó dára

Àdúrà gbogbo àwọn aráàlù ló gbé orílẹ̀-èdè yìí dé ibi tó dé lónìí, a ti gungi ré kọjá ewé.

Níbàyí, ẹ gba mi láyè láti sọ ọ̀rọ̀ díẹ̀ niípa ààrẹ àná, Ààrẹ Muhammadu Buhari, Ààrẹ mi, olóòtọ́ọ́ asáájú to gbiyanju pupọ fun orílẹ̀-èdè rẹ pẹ̀lú ìfẹ́ lẹ jẹ́, lóri bi a ṣe jẹ, ọ̀rẹ́ tòótó lo jẹ́ sí mi, Ìtàn o ni gbàgbé rẹ.

 

Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà sọ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Tinubu ní ìṣèjọbà oun yóò jẹ́ aṣoju ọmọ Naijiria ni nigba gbogbo ati pe awọn yoo maa gba ìmọ̀ràn káàkiri lóri ìgbésẹ̀ gbogbo tí àwọn bá fẹ́ gbé.

O ni oun ko ni fi ọ̀nà kọnà yan àwọn to bá òun díje du ipo ààrẹ nítorí pé ẹ̀tọ́ kan náà ni àwọn jumọ ní, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan naa làwọn jọ ń ja a fún. O fi kun un pe ẹtọ wọn ni igbesẹ ati tọ ile ẹjọ lọ ti wọn gbe, oun si fara mọ ọ.

Tinubu ni iṣejọba oun yoo mu idagbasoke to yẹ ba ihuwasi ati igbayegbadun gbogbo ọmọ Naijiria nipa mimojuto ọrọ aje, aparo kan ko ga jukan lọ.

Ó ní láìpẹ́ àwọn ìlànà ètò ọrọ̀ ajé ti ijọba oun fẹ gunle yoo bẹrẹ si ni jade sita faraalu lati ri.

Ààrẹ Tinubu ni iṣejọba oun yoo maa bọ̀wọ̀ fún ofin ni igba gbogbo, yóò si daabo bo Nàìjíríà lọ́wọ́ ìkọlù gbogbo

Bákan náà lo ni ọwọ yoo kan eto ọrọ aje pẹlu idaniloju lati mu idagbasoke ba ipese iṣẹ ati didopin ìṣẹ́ àti ìyà.

O ni awọn obinrin atawọn ọdọ yoo kopa to jọju ninu iṣejọba tuntun yii.

Ààrẹ Tinubu ni iṣẹ kiakia yóò waye lori eto abo nitori ko si bi eto ọrọ Aje ati ibọwọ fun ofin ṣe lee fi ẹsẹ rinlẹ laarin abo to mẹhẹ.

Ó ní atunto ilana ati eto abo pẹlu ipese koriya fun awọn oṣiṣẹ alaabo yoo moke.

Ó ní ìṣèjọba oun yoo tun mojuto ọrọ idaleeṣẹ silẹ, eyi to ni yoo le mu ki iye ọja ti a n ko lọ ta loke okun pọ ju iye ti wọn n ko wa ta lorilẹede Naijiria.

Lóri ọrọ ipese ina, o ni eto yoo kalẹ fun ipese ina o ni oun yoo ṣe eto ipese ina fun idagbasoke ọrọ aje araalu ati pe oun yoo ṣe koriya fun awọn ijọba ipinlẹ lati ṣe idasilẹ ileeṣẹ amunawa aladani tiwọn.

Bakan naa lo fi da awọn ileeṣẹ ati oludokoowo loju pe iṣejọba oun yoo ṣe agbyẹwo gbogbo ẹsun sisan owo ori lọna pupọ ati gbogbo awọn nnkan ipenija miran to n koju idokoowo silẹ.

O ni ileri oun lati pese iṣẹ miliọnu kan nipasẹ ẹka imọ ẹrọ ṣi duro dingbí.

Lóri ètò ọ̀gbìn, Ààrẹ Tinubu ni àwọn àwùjọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbín yóò wà káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti leè mú ki iye ọgbin to n jade lórílẹ̀èdè yii tubọ yanranti ki ounjẹ le pọ lọpọ yanturu faraalu.

O ni oun yoo tun tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ribiribi ti ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari gbe ṣe lẹka ipese ohun elo amayedẹrun.

Lori ọrọ owo iranwọ ori epo, Aarẹ tuntun lorilẹede Naijiria ṣalaye pe inu oun dun pe wọn ti yọ sisan owo iranwọ epo, subsidy ninu iṣuna ọdun yii eyi to fihan pe owo iranwọ ori epo ti rokun igbagbe.

Lori ọrọ paṣipaarọ owo ilẹ okeere, Aarẹ Tinubu sọ pe ko ni si ọja paṣipaarọ olojumeji mọ nitori pe banki apapọ labẹ iṣejọba oun yoo wọgile

Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó múlẹ̀, mo ṣèlérí pé, gbogbo ohun tí mo sọ yìí yóò wá sí ìmúṣe to rí pé orúkọ mi ni Bola Ahmed Tinubu, è mi sì ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Kí Ọlọ́run kó bùkún rẹ, kí ó sì bùkún ilẹ̀ wa.

 

George Oláyinká Akíntọ́lá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button