Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Yìí Rọ́ Àwọn Àdári Ilé-ẹ̀kọ́ Gíga Nàìjíríà Látí Ṣé Ìpolongo Ilé-ìwé Wọ́n

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 330

Ìgbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo tí rọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní Nàìjíríà látí ṣiṣẹ́ takuntakun fún ìgbéga àtí ọnà àtí máà gbá owó wọlé fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wọnyí nítori wípé kò sí Orílẹ̀-èdè kàn lágbayé tó lé ṣé ètò ìnáwó àwọn ilé-ìwé gíga wọnyí gẹ́gẹ́ bí ìyè tí wọ́n nílò.

Ó sọ èyí dì mímọ ní ọjọ́ Ìṣẹgun (Tuesday) nígbà tó ń ṣí gbangan nlá kán tí àjọ Kessington Adebukunola Adebutu Foundation, KAAF, kọ́ sí Ẹ̀kà Oúnjẹ Ènìyàn àtí Jíjẹ rẹ̀, ní Fásítì tí Ìbàdàn (Department of Human Nutrition and Dietetics, University of Ibadan).

Tún kà nípa:Àjọ Àgùnbánirọ̀ Òpó Ìsọkan Fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà: Ìgbákejì Ààrẹ Osinbajo.

Gbọ̀ngàn náà jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan, Sir Kessington Adebutu.

Ìgbákejì Ààrẹ tún ṣé ìdánilójú pé ètò ìṣúná owó ìjọ̀ba kìí yóò pèsè ìnáwó tó péye fún iṣẹ́ tó dára jùlọ tí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga nílò ní Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n náà tẹ́numọ́ pé o tí dì dandan fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga látí wáá ọnà àtí máà tajà látí rí owó tí wọ́n nílò.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button