Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-iṣẹ́ ológun Nàìjíríà fún Àwọn ẹgbẹ̀rin olùgbé Sókótó ní ìtọ́jú ọ̀fẹ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 299

Ilé-iṣẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà ikọ̀ kẹjọ ti fún àwọn ènìyàn tí ó ju ẹgbẹ̀rin lọ ní  agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Sifawa, Bodinga ati Denge-Shuni ní  Ìpínlẹ̀ Sókótó ní ìtọ́jú ọ̀fẹ́.

Nigba ti o n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, Oludari Alakoso gbogbogboo ikọ kẹjọ  Sokoto,Ajagun Uwem Bassey, sọ pe ipilẹṣẹ naa wa lati tunbọ mu  ilọsiwaju ba awọn iranlọwọ ti  ile-iṣẹ ọmọ ogun Naijiria n ṣe  lati mu irọrun ba awọn eniyan.

Eyi si jẹ itesiwaju ninu awọn eto iṣami Ayẹyẹ Ọjọ ayajọ Ọmọ-ogun Naijiria ti ọdun yii, ti Ẹgbẹ ti ṣeto.

Ogagun ologun, eni ti oga agba ajagun, Ralph Nnebife,ṣoju sọ pe ìṣe naa kii ṣe lasiko Ajọyọ ọjọ ayajọ ologun nikan sugbon ti o jẹ aṣa  ologun Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button