Àjọ tẹ̀síwájú lórí ìṣètọ́jú ìgbẹ́ gbuuru èwe Ní Sókótó, Kánò
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Láti pa ìgbé gbuuru èwe kúrò ní Àríwá Nàìjíríà, Ẹgbẹ́ tí kìí ṣe tìjọba, Wellbeing Foundation Africa sọ pé, ó ti ṣe àṣeyọrí ní ìpele àkọ́kọ́ ti ‘Scaling Up Zinc and Low-Osmolarity Oral Rehydration Solution’ tí wọ́n ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ fún Ìtọ́jú Àrùn Ìgbẹ́ gbuuru èwe ní Àríwá Nàìjíríà.
Aarẹ-Oludasilẹ, Iyaafin Toyin Ọjọra Sakari, ti o sọ eyi nibi apejọ ọlọjọ mẹta, labẹ titẹsiwaju lati maa lo Zinc ati LO-ORS fun itọju gbuuru ọmọde ninu iṣẹ akanṣe Ariwa Naijiria,ti ijọba Canada gbowo kalẹ fun, sọ pe. Ajo naa ri erogba Fund Revolving Drug, (DRF) gẹgẹ bi igbesẹ pataki lati mu igbega ba alafia gbogbo eniyan ti o n lo oogun ati awọn iṣẹ iṣegun.
Ajọ naa la awọn ilana ti o ṣe lati ṣe mu wa larọwọto silẹ,pipese rẹ ati iṣakoso Akojọ Awọn oogun Pataki Naijiria, pẹlu erongba lati pese DRF/DMA to dangajia.
O ṣe akiyesi pe apakan iṣẹ akanṣe naa, eyiti o bẹrẹ ni Oṣu Kẹjọ ọdun 2021,ti ṣaṣeyọri pataki ninu iṣakoso ati itọju igbẹ gbuuru ni ipinlẹ Kano ati Sokoto.
Leave a Reply