Ní agbègbè Rutshuru, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Krìsítíánì ni inú wọn kò dùn lọ́jọ́ Jimọh ‘good Friday’.
Pelu ayẹyẹ nla ọdun ajinde,awọn ọmọ orilẹ-ede Congo lati iha ila-oorun DRC ko le ṣayẹyẹ naa.
Ẹgbẹ ọlọtẹ M23 ti o ja ogun ni agbegbe North-Kivu jẹ ki ẹgbẹrun mẹrindin-logoji sa kuro ni orilẹ-ede naa.
Gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye UN,ṣe sọ awọn ti o ju ẹgbẹrun mẹwa lọ lo morile Uganda.
Nígbàtí òpin ìforígbárí ní àwọn àgbègbè kan bá ti mú àwọn ará abúlé kan padà wá, àwọn mìíràn kò kúrò níbẹ̀ rárá, inú wọn sì dùn pé wọ́n la ìjà náà já.
ọpọlọpọ awọn olugbe Rutushuru ni wọn ko ni anfaani lati pejọ nitori ipo ti ilu wa ati isede.
Ninu ọrọ Ọjọ ajinde Kristi rẹ, Pope Francis ranti awọn olufaragba ogun ni DRC, o gbadura pe ki alaafia o jọba.
Leave a Reply