Olùdámọ́rán pàtàkì fún ààrẹ lórí ìròyìn àti ìkéde,Fẹ́mi Adéṣínà,sọ pé,ààrẹ ti ṣe àṣeyọrí tó tayọ t’àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lórí àkójọ èrè Ilé -iṣẹ́ tó ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ Epo ní Orílẹ̀ –èdè Nàìjíríà NNPC, tí ó tún jẹ́ Mínísítà fún , ní ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún mẹ́rìnlé-lógójì.
Femi Adesina, sọ pe aarẹ, fun idi eyi, ti ṣe nnkan tawọn aṣiwaju rẹ ṣeti lori ile-iṣẹ to n mojuto eto epo ilẹ NNPC, ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, bakannan, o tun ja awọn ide miiran.
O sọ pe: “ide nla kan ti o ja laipẹ ni ti Ile-iṣẹ to n mojuto ọrọ Epo ilẹ Orilẹ-ede Naijiria (NNPC), to kede èrè rẹ lapapọ, akọkọ iru rẹ ninu itan ile-iṣẹ ọhun ni ọdun mẹrinle-logoji. Labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari, ti o tun jẹ Minisita fun Awọn orisun Epo ilẹ, ile-iṣẹ ọhun kede ere akọkọ iru rẹ ti o jẹ meétalá- din- lẹ ẹ̀wá- dinlọ́ọ̀dúnrún biliọnu Naira,ni eyi ti ko ṣẹlẹ ri.
‘Ṣugbọn iyẹn kii ṣe ide pataki kan ṣoṣo ti o ja ni igbesi aye ijọba Buhari. Wọn pọ. Wọn pọ lọpọ yanturu ti ko si ṣee ka. ”
Leave a Reply