Ìyanṣẹ́lódì àwọn dókítà: A ti Ṣe àṣeyọrí tó nítumọ̀ -–Mínísítà ètò Iṣẹ́
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìjọba orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà sọ pé òhun ti yanjú gbogbo àwọn nǹkan tí àwọn dókítà Oníségùn ń bèèrè fún, àyàfi èyí tí ó lòdì sófin “kò sí iṣẹ́ kò sáwó”.
Nitorinaa, ijọba n kepe awọn ọmọ ẹgbẹ dokita lapapọ lati fopin si iyanṣẹlodi ti wọn bẹrẹ lati bii ọjọ mẹtale-lọgbọn.
Minisita fun eto Iṣẹ ati ironilagbara, Dokita Chris Ngige ṣalaye eyi fun awọn oniroyin Ile -ilu lẹhin ti o ṣe ipade bonkẹlẹ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari.
O sọ pe ijọba orilẹ -ede Naijiria ko ni lọwọ ninu iru adehun bẹẹ tabi iru ibeere bẹ.
Minisita naa sọ pe, o ṣeni laanu pe, idaṣẹsilẹ ọhun ti n pẹ, nigba miiran, awọn eniyan to n ṣe awọn iṣẹ pataki bi eka ilera ko kii kan daṣẹsilẹ lainidii.
Leave a Reply