Ìjọba orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tuntun pẹ̀lú ètò àjọ àgbáyé ní orílẹ̀ -èdè, láti mú ìlọwọ́sí bá ẹ̀tọ̀ ọmọnìyàn ní orílẹ̀ -èdè náà.
Ninu ijiroro kan ti wọn filọlẹ ni Ilu Abuja ni ọjọ iṣẹgun, awọn ẹgbẹ mejeeji bẹrẹ ijiroro lori bi wọn ṣe le rii pe aabo to daju wa fun ẹtọ, ati imuse awọn apejọ ati awọn ofin lori awọn ẹtọ ọmọniyan, eyiti Naijiria fọwọsi.
Nigbati o n soro nibi ifilọlọ naa , aarẹ ajọ agbaye UN ni Naijiria, Edward Kallon, sọ pe aabo ẹtọ ọmọniyan jẹ ọkan pataki ti ajọ agbaye UN lọwọsi.
Kallon, ti o ṣe aṣoju fun Peter Hawkins, Aṣoju Orilẹ -ede ti UNICEF, sọ pe Naijiria, gẹgẹ bii ọpọlọpọ awọn orilẹ -ede miiran, dojuko ọpọlọpọ awọn italaya ẹtọ ọmọniyan ti wọn ni lati yanju.
O salaye pe ijumọsọrọ pẹlu ijọba, yoo ṣe iranlọwọ lori awọn akitiyan UN fun ilosiwaju ẹtọ ọmọniyan.
Kallon tọka si pe,lati ṣaṣeyọri ,wọn gbọdọ dojukọ didasilẹ eto ilana kan ti yoo maa ṣepade lorekore lati ṣe apapọ ayẹwo ifọwọsowọpọ lori awọn ọrọ to ba jẹyọ lori ẹtọ ọmọniyan ni Naijiria.
Leave a Reply